Esekiẹli 32

Èmi yóò da ọkàn ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn rú nígbà tí mo bá mú ìparun rẹ wá ní àárín àwọn orílẹ̀-èdè tí ìwọ kò í tí ì mọ̀.

Ezekiel 32:9 (UKJV) I will also vex the hearts of many people, when I shall bring your destruction among the nations, into the countries which you have not known.

7Nígbà tí mo bá fọ́n ọ jáde, èmi yóò pa ọ̀run dé àwọn ìràwọ̀ wọn yóò sì ṣókùnkùn; èmi yóò sì fi ìkùùkuu bo oòrùn òṣùpá kì yóò sì tan ìmọ́lẹ̀ rẹ̀.

8Gbogbo ìmọ́lẹ̀ títàn ní ojú ọ̀run ni èmi yóò mú ṣókùnkùn lórí rẹ; èmi yóò mú òkùnkùn wá sórí ilẹ̀ rẹ, ni Olúwa Olódùmarè wí.

9Èmi yóò da ọkàn ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn rú nígbà tí mo bá mú ìparun rẹ wá ní àárín àwọn orílẹ̀-èdè tí ìwọ kò í tí ì mọ̀.

10Èmi yóò mú kí ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn dẹ́rùbà ọ́, àwọn ọba wọn yóò sì wárìrì fún ìbẹ̀rù pẹ̀lú ìpayà nítorí rẹ, nígbà tí mo bá ju idà mi ní iwájú wọn. Ní ọjọ́ ìṣubú rẹ ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú wọn yóò wárìrì ní gbogbo ìgbà fún ẹ̀mí rẹ.

11“ ‘Nítorí èyí yìí ní Olúwa Olódùmarè wí: “ ‘Idà ọba Babeli yóò wá sí orí rẹ,

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.