12nínú àwọn ọmọ Asgadi: Johanani ọmọ Hakatani, àti àádọ́fà ọkùnrin pẹ̀lú rẹ̀;
13nínú àwọn ọmọ Adonikami: àwọn ti ó gbẹ̀yìn, tì orúkọ wọn ń jẹ́ Elifaleti, Jeieli àti Ṣemaiah, àti ọgọ́ta ọkùnrin pẹ̀lú wọn;
14nínú àwọn ọmọ Bigfai: Uttai àti Sakkuri, àti àádọ́rin ọkùnrin pẹ̀lú wọn.
15Èmi kó wọn jọ pọ̀ si etí odò ti ń sàn lọ sí Ahafa, a pàgọ́ síbẹ̀ fún odidi ọjọ́ mẹ́ta, nígbà ti mo wo àárín àwọn ènìyàn àti àárín àwọn àlùfáà, ń kò rí ọmọ Lefi kankan níbẹ̀.
16Nígbà náà ni mo pe Elieseri, Arieli, Ṣemaiah, Elnatani, Jaribi, Elnatani, Natani, Sekariah, àti Meṣullamu, tí wọ́n jẹ́ olórí, àti Joiaribu àti Elnatani tí wọ́n jẹ́ onímọ̀ ìjìnlẹ̀,