Esra 8

Nígbà náà ni mo pe Elieseri, Arieli, Ṣemaiah, Elnatani, Jaribi, Elnatani, Natani, Sekariah, àti Meṣullamu, tí wọ́n jẹ́ olórí, àti Joiaribu àti Elnatani tí wọ́n jẹ́ onímọ̀ ìjìnlẹ̀,

Ezra 8:16 (UKJV) Then sent I for Eliezer, for Ariel, for Shemaiah, and for Elnathan, and for Jarib, and for Elnathan, and for Nathan, and for Zechariah, and for Meshullam, chief men; also for Joiarib, and for Elnathan, men of understanding.

14nínú àwọn ọmọ Bigfai: Uttai àti Sakkuri, àti àádọ́rin ọkùnrin pẹ̀lú wọn.

15Èmi kó wọn jọ pọ̀ si etí odò ti ń sàn lọ sí Ahafa, a pàgọ́ síbẹ̀ fún odidi ọjọ́ mẹ́ta, nígbà ti mo wo àárín àwọn ènìyàn àti àárín àwọn àlùfáà, ń kò rí ọmọ Lefi kankan níbẹ̀.

16Nígbà náà ni mo pe Elieseri, Arieli, Ṣemaiah, Elnatani, Jaribi, Elnatani, Natani, Sekariah, àti Meṣullamu, tí wọ́n jẹ́ olórí, àti Joiaribu àti Elnatani tí wọ́n jẹ́ onímọ̀ ìjìnlẹ̀,

17mo sì rán wọn tí àwọn ti àṣẹ sí ọ̀dọ̀ Iddo, tí ó jẹ́ olórí ní ibi ti a ń pè ni Kasifia, mo sì sọ fún wọn ohun tí wọn yóò wí fun Iddo àti àwọn Lefi arákùnrin rẹ̀, tí wọ́n jẹ́ òṣìṣẹ́ tẹmpili ní Kasifia pé, kí wọn mú àwọn ìránṣẹ́ wá sí ọ̀dọ̀ wa fún ilé Ọlọ́run wa.

18Nítorí ọwọ́ àánú Ọlọ́run wa wà lára wa, wọ́n sì mú Ṣerebiah wá fún wa, ẹni tí ó kún ojú òsùwọ̀n láti ìran Mahili, ọmọ Lefi, ọmọ Israẹli, àti àwọn ọmọ Ṣerebiah àti àwọn arákùnrin rẹ̀, wọ́n jẹ́ ọkùnrin méjìdínlógún.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.