24Àwọn ọmọ Sibeoni: Aiah àti Ana. Èyí ni Ana tí ó rí ìsun omi gbígbóná ní inú aginjù bí ó ti ń da àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ Ṣebeoni baba rẹ̀.
25Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Ana: Diṣoni àti Oholibama ọmọbìnrin Ana.
26Àwọn ọmọ Diṣoni ni: Hemdani, Eṣbani, Itrani àti Kerani.
27Àwọn ọmọ Eseri: Bilhani, Saafani àti Akani.
28Àwọn ọmọ Diṣani ni: Usi àti Arani.