Gẹnẹsisi 36

Ó sì tún fẹ́ Basemati ọmọ Iṣmaeli arábìnrin Nebaioti.

Genesis 36:3 (UKJV) And Bashemath Ishmael's daughter, sister of Nebajoth.

1Wọ̀nyí ni ìran Esau, ẹni tí a ń pè ní Edomu.

2Nínú àwọn ọmọbìnrin Kenaani ni Esau ti fẹ́ àwọn ìyàwó rẹ̀: Adah ọmọbìnrin Eloni ará Hiti àti Oholibama, ọmọbìnrin Ana, ọmọ ọmọ Sibeoni ará Hifi.

3Ó sì tún fẹ́ Basemati ọmọ Iṣmaeli arábìnrin Nebaioti.

4Adah bí Elifasi fún Esau, Basemati sì bí Reueli,

5Oholibama pẹ̀lú sì bí Jeuṣi, Jalamu, àti Kora. Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ tí Esau bí ní Kenaani.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.