Habakuku 2

Ṣùgbọ́n Olúwa wà nínú tẹmpili mímọ́ rẹ̀; ẹ jẹ́ kí gbogbo ayé parọ́rọ́ níwájú rẹ.

Habakkuk 2:20 (UKJV) But the LORD is in his holy temple: let all the earth keep silence before him.

18“Èrè kí ni òrìṣà ni, tí oníṣọ̀nà rẹ̀ fi gbẹ́ ẹ, ère dídá ti ń kọ ni èké? Nítorí ti ẹni ti ó dá a gbẹ́kẹ̀ rẹ̀ lé ohun tí ó fúnra rẹ̀ dá; ó sì mọ ère tí kò le fọhùn.

19Ègbé ni fún ẹni ti ń sọ fún igi pé, ‘Di alààyè?’ Fún òkúta tí kò lè fọhùn pé, ‘Dìde.’ Ǹjẹ́ òun lè tọ́ ni sí ọ̀nà? Wúrà àti fàdákà ni a fi bò ó yíká; kò sì sí èémí kan nínú rẹ.”

20Ṣùgbọ́n Olúwa wà nínú tẹmpili mímọ́ rẹ̀; ẹ jẹ́ kí gbogbo ayé parọ́rọ́ níwájú rẹ.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.