Hosea 2

“Sọ fún àwọn arákùnrin rẹ, ‘Ènìyàn mi,’ kí o sì wí fún àwọn arábìnrin rẹ ‘Àyànfẹ́ mi.’

Hosea 2:1 (UKJV) Say all of you unto your brethren, Ammi; and to your sisters, Ruhamah.

1“Sọ fún àwọn arákùnrin rẹ, ‘Ènìyàn mi,’ kí o sì wí fún àwọn arábìnrin rẹ ‘Àyànfẹ́ mi.’

2“Ẹ bá ìyá yín wí, ẹ bá a wí, nítorí pé kì í ṣe ìyàwó mi, Èmi náà kì í sì í ṣe ọkọ rẹ̀. Jẹ́ kí ó yọ àgbèrè rẹ̀ kúrò lójú rẹ̀ àti àìṣòótọ́ kúrò ní àyà rẹ̀.

3Àìṣe bẹ́ẹ̀ èmi yóò tú u sí ìhòhò, Èmi yóò sì gbé e kalẹ̀ bí ọjọ́ tí a bí i. Èmi yóò ṣe ọ́ bí i aṣálẹ̀ ilẹ̀, Èmi yóò sì sọ ọ́ di ìyàngbẹ ilẹ̀ Èmi yóò sì fi òǹgbẹ gbẹ ẹ́.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.