1nígbà tí èmi ìbá mú Israẹli láradá. Ẹ̀ṣẹ̀ Efraimu ń farahàn ìwà búburú Samaria sì ń hàn síta. Wọ́n ń ṣe ẹ̀tàn, àwọn olè ń fọ́ ilé; àwọn ọlọ́ṣà ń jalè ní òpópónà;
2ṣùgbọ́n wọn kò mọ̀ pé mo rántí gbogbo ìwà búburú wọn. Ẹ̀ṣẹ̀ wọn gbé wọn mì pátápátá; wọ́n wà níwájú mi nígbà gbogbo.
3“Wọ́n ń mú inú ọba dùn pẹ̀lú ìwà búburú wọn, àti inú ọmọ-aládé dùn pẹ̀lú irọ́ wọn.
4Alágbèrè ni gbogbo wọn wọ́n gbóná bí ààrò àkàrà tí a dáwọ́ kíkoná dúró, lẹ́yìn ìgbà tí o ti pò ìyẹ̀fun tán, títí ìgbà tí yóò wú.
5Ní ọjọ́ àjọ̀dún ọba wa wáìnì mú ara ọmọ-aládé gbóná ó sì darapọ̀ mọ́ àwọn oníyẹ̀yẹ́.