28Wọ́n wọ Aiati, wọ́n gba Migroni kọjá, wọ́n kó nǹkan pamọ́ sí Mikmasi.
29Wọ́n ti rékọjá ọ̀nà, wọ́n wí pé, “Àwa ó tẹ̀dó sí Geba lóru yìí.” Rama mì tìtì Gibeah ti Saulu sálọ.
30Gbé ohùn rẹ sókè, ìwọ ọmọbìnrin Galimu! Dẹ etí sílẹ̀, ìwọ Laiṣa! Ìwọ òtòṣì Anatoti!
31Madmena ti fẹsẹ̀ fẹ́ ẹ, àwọn ènìyàn Gebimu ti fi ara pamọ́.
32Ní ọjọ́ yìí, wọn yóò dúró ní Nobu wọn yóò kan sáárá, ní òkè ọmọbìnrin Sioni ní òkè Jerusalẹmu.