Isaiah 19

Àwọn tí ó ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ọ̀gbọ̀ yóò kọminú àwọn ahunṣọ ọ̀gbọ̀ yóò sọ ìrètí nù.

Isaiah 19:9 (UKJV) Moreover they that work in fine flax, and they that weave networks, shall be confounded.

7àwọn igi ipadò Naili pẹ̀lú, tí ó wà ní orísun odò, gbogbo oko tí a dá sí ipadò Naili yóò gbẹ dànù tí yóò sì fẹ́ dànù tí kò sì ní sí mọ́.

8Àwọn apẹja yóò sọkún kíkorò, àti gbogbo àwọn tí ó ń ju ìwọ̀ sínú odò; odò náà yóò sì máa rùn.

9Àwọn tí ó ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ọ̀gbọ̀ yóò kọminú àwọn ahunṣọ ọ̀gbọ̀ yóò sọ ìrètí nù.

10Àwọn tí ń ṣiṣẹ́ aṣọ yóò rẹ̀wẹ̀sì, gbogbo àwọn oníṣẹ́ oṣù ni àìsàn ọkàn yóò ṣe.

11Àwọn oníṣẹ́ Ṣoani ti di aláìgbọ́n, àwọn ọlọ́gbọ́n olùdámọ̀ràn Farao ń mú ìmọ̀ràn àìgbọ́n wá. Báwo ló ṣe lè sọ fún Farao pé, “Mo jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn, ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn àwọn ọba àtijọ́.”

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.