Isaiah 19

Àwọn apẹja yóò sọkún kíkorò, àti gbogbo àwọn tí ó ń ju ìwọ̀ sínú odò; odò náà yóò sì máa rùn.

Isaiah 19:8 (UKJV) The fishers also shall mourn, and all they that cast angle into the brooks shall lament, and they that spread nets upon the waters shall languish.

6Adágún omi yóò sì di rírùn; àwọn odò ilẹ̀ Ejibiti yóò máa dínkù wọn yóò sì gbẹ. Àwọn koríko odò àti ìrẹ̀tẹ̀ yóò gbẹ,

7àwọn igi ipadò Naili pẹ̀lú, tí ó wà ní orísun odò, gbogbo oko tí a dá sí ipadò Naili yóò gbẹ dànù tí yóò sì fẹ́ dànù tí kò sì ní sí mọ́.

8Àwọn apẹja yóò sọkún kíkorò, àti gbogbo àwọn tí ó ń ju ìwọ̀ sínú odò; odò náà yóò sì máa rùn.

9Àwọn tí ó ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ọ̀gbọ̀ yóò kọminú àwọn ahunṣọ ọ̀gbọ̀ yóò sọ ìrètí nù.

10Àwọn tí ń ṣiṣẹ́ aṣọ yóò rẹ̀wẹ̀sì, gbogbo àwọn oníṣẹ́ oṣù ni àìsàn ọkàn yóò ṣe.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.