Isaiah 19

Adágún omi yóò sì di rírùn; àwọn odò ilẹ̀ Ejibiti yóò máa dínkù wọn yóò sì gbẹ. Àwọn koríko odò àti ìrẹ̀tẹ̀ yóò gbẹ,

Isaiah 19:6 (UKJV) And they shall turn the rivers far away; and the brooks of defence shall be emptied and dried up: the reeds and flags shall wither.

4Èmi yóò fi Ejibiti lé agbára àwọn ìkà amúnisìn lọ́wọ́, ọba aláìláàánú ni yóò jẹ ọba lé wọn lórí,” ni Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.

5Gbogbo omi inú odò ni yóò gbẹ, gbogbo ilẹ̀ àyíká odò ni yóò gbẹ tí yóò sì sáàpá.

6Adágún omi yóò sì di rírùn; àwọn odò ilẹ̀ Ejibiti yóò máa dínkù wọn yóò sì gbẹ. Àwọn koríko odò àti ìrẹ̀tẹ̀ yóò gbẹ,

7àwọn igi ipadò Naili pẹ̀lú, tí ó wà ní orísun odò, gbogbo oko tí a dá sí ipadò Naili yóò gbẹ dànù tí yóò sì fẹ́ dànù tí kò sì ní sí mọ́.

8Àwọn apẹja yóò sọkún kíkorò, àti gbogbo àwọn tí ó ń ju ìwọ̀ sínú odò; odò náà yóò sì máa rùn.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.