4Gbẹ́kẹ̀lé Olúwa títí láé, nítorí Olúwa, Olúwa ni àpáta ayérayé náà.
5Ó sọ àwọn tí ó ń gbé ní òkè di onírẹ̀lẹ̀ ó rẹ ìlú agbéraga náà nílẹ̀; ó sọ ọ́ di ilẹ̀ pẹrẹsẹ ó sì sọ ọ́ sílẹ̀ nínú erùpẹ̀.
6Ẹsẹ̀ tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀ ẹsẹ̀ aninilára n nì, ipasẹ̀ àwọn òtòṣì.
7Ipa ọ̀nà àwọn olódodo tẹ́jú, ìwọ tó dúró ṣinṣin, ìwọ mú ọ̀nà àwọn olódodo ṣe geere.
8Bẹ́ẹ̀ ni, Olúwa, rírìn ní ọ̀nà òfin rẹ àwa dúró dè ọ́; orúkọ rẹ àti òkìkí rẹ àwọn ni ohun tí ọkàn wa ń fẹ́.