Isaiah 28

Ọlọ́run rẹ̀ tọ́ ọ ṣọ́nà ó sì kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ ní ọ̀nà tó tọ́.

Isaiah 28:26 (UKJV) For his God does instruct him to discretion, and does teach him.

24Nígbà tí àgbẹ̀ kan bá tu ilẹ̀ láti gbìn yóò ha máa tulẹ̀ títí bi? Ǹjẹ́ yóò ha máa tu ilẹ̀ kí ó sì máa jọ̀ ọ́ títí lọ bí?

25Nígbà tí òun bá ti tẹ́ ojú ilẹ̀ rẹ̀ pẹrẹsẹ òun kò ha ń fúnrúgbìn dílì kí ó sì fúnrúgbìn kummini ká? Kí ó sì gbin alikama lẹ́sẹẹsẹ, barle tí a yàn, àti spelti ní ipò rẹ̀?

26Ọlọ́run rẹ̀ tọ́ ọ ṣọ́nà ó sì kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ ní ọ̀nà tó tọ́.

27Nítorí a kò fi ohun èlò ìpakà dili, bẹ́ẹ̀ ni a kì í yí kẹ̀kẹ́ ẹrù kiri lórí kummini; ṣùgbọ́n ọ̀pá ni a fi ń pa dili jáde, ọ̀gọ ni a sì lu kummini.

28A gbọdọ̀ lọ ìyẹ̀fun kí a tó ṣe àkàrà; bẹ́ẹ̀ ni ẹnìkan kì í máa pa á lọ títí láé. Bí ó tilẹ̀ yí ẹsẹ̀ kẹ̀kẹ́ ìpakà a rẹ̀ lórí i rẹ̀, àwọn ẹṣin rẹ̀ kò le lọ̀ ọ́.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.