Isaiah 29

Lẹ́ẹ̀kan sí i àwọn onírẹ̀lẹ̀ yóò yọ̀ nínú Olúwa: àwọn aláìní yóò yọ̀ nínú Ẹni Mímọ́ ti Israẹli.

Isaiah 29:19 (UKJV) The meek also shall increase their joy in the LORD, and the poor among men shall rejoice in the Holy One of Israel.

17Ní àìpẹ́ jọjọ, ǹjẹ́ a kò ní sọ Lebanoni di pápá ẹlẹ́tù lójú àti pápá ẹlẹ́tù lójú yóò dàbí aginjù?

18Ní ọjọ́ náà adití yóò gbọ́ ọ̀rọ̀ ìwé kíká náà, láti inú fìrífìrí àti òkùnkùn ni àwọn ojú afọ́jú yóò ríran.

19Lẹ́ẹ̀kan sí i àwọn onírẹ̀lẹ̀ yóò yọ̀ nínú Olúwa: àwọn aláìní yóò yọ̀ nínú Ẹni Mímọ́ ti Israẹli.

20Aláìláàánú yóò pòórá, àwọn tí ń ṣẹlẹ́yà yóò di àwátì, gbogbo àwọn tí ó ní ojú ibi ni a ó ké lulẹ̀—

21àwọn tí wọ́n fi ọ̀rọ̀ kan mú ẹnìkan di ẹlẹ́bi, ẹni tí ń dẹkùn mú olùgbèjà ní ilé ẹjọ́ tí ẹ fi ẹ̀rí èké dun aláìṣẹ̀ ní ìdájọ́.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.