Isaiah 32

Ẹ lu ọmú yín fún pápá ìgbádùn náà, fún àwọn àjàrà eléso

Isaiah 32:12 (UKJV) They shall lament for the teats, for the pleasant fields, for the fruitful vine.

10Ní ó lé díẹ̀ ní ọdún kan ẹ̀yin tí ọkàn an yín balẹ̀ yóò wárìrì; ìkórè àjàrà kò ní múnádóko, bẹ́ẹ̀ ni ìkórè èso kò ní sí.

11Wárìrì, ẹ̀yin obìnrin onítẹ̀lọ́rùn; bẹ̀rù, ẹ̀yin ọ̀dọ́mọbìnrin tí ẹ rò pé ọkàn yín balẹ̀! Ẹ bọ́ aṣọ yín kúrò, ẹ ró aṣọ ọ̀fọ̀ mọ́ ẹ̀gbẹ́ yín.

12Ẹ lu ọmú yín fún pápá ìgbádùn náà, fún àwọn àjàrà eléso

13àti fún ilẹ̀ àwọn ènìyàn mi, ilẹ̀ tí ó ti kún fún ẹ̀gún àti ẹ̀wọ̀n, bẹ́ẹ̀ ni, kẹ́dùn fún gbogbo ilé ìtura àti fún ìlú àríyá yìí.

14Ilé olódi ni a ó kọ̀sílẹ̀, ìlù aláriwo ni a ó kọ̀ tì; ilé olódi àti ilé ìṣọ́ ni yóò di ihò títí láéláé, ìdùnnú àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àti pápá oko fún àwọn ẹran ọ̀sìn,

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.