Isaiah 33

Nínú èrò rẹ ìwọ yóò rántí ẹ̀rù rẹ àtẹ̀yìnwá: “Níbo ni ọ̀gá àgbà náà wà? Níbo ni ẹni tí ń gba owó òde wà? Níbo ni òṣìṣẹ́ ti ó ń mójútó ilé ìṣọ́ wà?”

Isaiah 33:18 (UKJV) Yours heart shall meditate terror. Where is the scribe? where is the receiver? where is he that counted the towers?

16Òun náà yóò gbé ní ibi gíga, ibi ààbò rẹ̀ yóò jẹ́ òkè ńlá olódi. A ó mú oúnjẹ fún un, omi rẹ̀ yóò sì dájú.

17Ojú rẹ yóò rí ọba nínú ẹwà rẹ̀ yóò sì rí ilẹ̀ kan tí ó tẹ́ lọ rẹrẹẹrẹ.

18Nínú èrò rẹ ìwọ yóò rántí ẹ̀rù rẹ àtẹ̀yìnwá: “Níbo ni ọ̀gá àgbà náà wà? Níbo ni ẹni tí ń gba owó òde wà? Níbo ni òṣìṣẹ́ ti ó ń mójútó ilé ìṣọ́ wà?”

19Ìwọ kì yóò rí àwọn agbéraga ènìyàn mọ́, àwọn ènìyàn tí èdè wọn fi ara sin, pẹ̀lú ahọ́n tí ó ṣàjèjì tí kò sì yé ni.

20Gbójú sókè sí Sioni, ìlú àjọ̀dún wa, ojú rẹ yóò rí Jerusalẹmu, ibùgbé àlàáfíà n nì, àgọ́ tí a kò ní yí padà; àwọn òpó rẹ̀ ni a kì yóò fàtu tàbí èyíkéyìí nínú okùn rẹ̀ kí já.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.