Isaiah 33

A gbé Olúwa ga, nítorí pé ó ń gbé ibi gíga, Òun yóò kún Sioni pẹ̀lú ẹ̀tọ́ àti òdodo.

Isaiah 33:5 (UKJV) The LORD is exalted; for he dwells on high: he has filled Zion with judgment and righteousness.

3Ní ìkérara ohùn rẹ, àwọn ènìyàn sá, nígbà tí o dìde sókè, àwọn orílẹ̀-èdè fọ́nká.

4Ìkógun rẹ, ìwọ orílẹ̀-èdè ni a kórè gẹ́gẹ́ bí i ti ọ̀dọ́ eṣú; gẹ́gẹ́ bí àkójọpọ̀ eṣú, àwọn ènìyàn wọ ibẹ̀.

5A gbé Olúwa ga, nítorí pé ó ń gbé ibi gíga, Òun yóò kún Sioni pẹ̀lú ẹ̀tọ́ àti òdodo.

6Òun yóò jẹ́ ìpìlẹ̀ tí ó dájú fún àkókò rẹ ibùjókòó ìgbàlà kíkún àti ọgbọ́n òun ìmọ̀; ìbẹ̀rù Olúwa ni kọ́kọ́rọ́ sí ìṣúra yìí.

7Wò ó, àwọn onígboyà ọkùnrin wọn pohùnréré ẹkún ní òpópónà; àwọn ikọ̀ àlàáfíà sọkún kíkorò.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.