Isaiah 38

Èmi wí pé, “Ní àárín gbùngbùn ọjọ́ ayé mi èmi ó ha kọjá lọ ní ibodè ikú kí a sì dùn mí ní àwọn ọdún mi tí ó ṣẹ́kù?”

Isaiah 38:10 (UKJV) I said in the cutting off of my days, I shall go to the gates of the grave: I am deprived of the residue of my years.

8Èmi yóò mú òjìji oòrùn kí ó padà sẹ́yìn ní ìṣísẹ̀ mẹ́wàá nínú èyí tí ó fi sọ̀kalẹ̀ ní ibi àtẹ̀gùn ti Ahasi.’ ” Bẹ́ẹ̀ ni oòrùn padà sẹ́yìn ní ìṣísẹ̀ mẹ́wàá sí ibi tí ó ti dé tẹ́lẹ̀.

9Ìwé tí Hesekiah ọba Juda kọ lẹ́yìn àìsàn rẹ̀ nígbà tí ó ti gbádùn tán.

10Èmi wí pé, “Ní àárín gbùngbùn ọjọ́ ayé mi èmi ó ha kọjá lọ ní ibodè ikú kí a sì dùn mí ní àwọn ọdún mi tí ó ṣẹ́kù?”

11Èmi wí pé, “Èmi kì yóò lè tún rí Olúwa mọ́, àní Olúwa, ní ilẹ̀ àwọn alààyè; èmi kì yóò lè síjú wo ọmọ ènìyàn mọ́, tàbí kí n wà pẹ̀lú àwọn tí ó sì ń gbe orílẹ̀ ayé báyìí.

12Gẹ́gẹ́ bí àgọ́ olùṣọ́-àgùntàn, ilé mi ni a ti wó lulẹ̀ tí a sì gbà kúrò lọ́wọ́ mi. Gẹ́gẹ́ bí ahunṣọ mo ti ká ayé mi nílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni òun sì ti ké mi kúrò lára àṣà; ọ̀sán àti òru ni ìwọ ṣe òpin mi.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.