Isaiah 38

Èmi dún gẹ́gẹ́ bí àkọ̀ tàbí alápáǹdẹ̀dẹ̀, èmi káàánú gẹ́gẹ́ bí aṣọ̀fọ̀ àdàbà. Ojú mi rẹ̀wẹ̀sì gẹ́gẹ́ bí mo ti ń wo àwọn ọ̀run. Ìdààmú bá mi, Ìwọ Olúwa, wá fún ìrànlọ́wọ́ mi!”

Isaiah 38:14 (UKJV) Like a crane or a swallow, so did I chatter: I did mourn as a dove: mine eyes fail with looking upward: O LORD, I am oppressed; undertake for me.

12Gẹ́gẹ́ bí àgọ́ olùṣọ́-àgùntàn, ilé mi ni a ti wó lulẹ̀ tí a sì gbà kúrò lọ́wọ́ mi. Gẹ́gẹ́ bí ahunṣọ mo ti ká ayé mi nílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni òun sì ti ké mi kúrò lára àṣà; ọ̀sán àti òru ni ìwọ ṣe òpin mi.

13Èmi fi sùúrù dúró títí di àfẹ̀mọ́júmọ́, ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí kìnnìún ó ti fọ́ gbogbo egungun mi; ọ̀sán àti òru ni ìwọ fi ṣe òpin mi.

14Èmi dún gẹ́gẹ́ bí àkọ̀ tàbí alápáǹdẹ̀dẹ̀, èmi káàánú gẹ́gẹ́ bí aṣọ̀fọ̀ àdàbà. Ojú mi rẹ̀wẹ̀sì gẹ́gẹ́ bí mo ti ń wo àwọn ọ̀run. Ìdààmú bá mi, Ìwọ Olúwa, wá fún ìrànlọ́wọ́ mi!”

15Ṣùgbọ́n kí ni èmi lè sọ? Òun ti bá mi sọ̀rọ̀ àti pé òun tìkára rẹ̀ ló ti ṣe èyí. Èmi yóò máa rìn ní ìrẹ̀lẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ mi nítorí ìpọ́njú ẹ̀mí mi yìí.

16Olúwa, nípa nǹkan báwọ̀nyí ni àwọn ènìyàn ń gbé; àti pé ẹ̀mí mi rí iyè nínú wọn pẹ̀lú. Ìwọ dá ìlera mi padà kí o sì jẹ́ kí n wà láààyè.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.