Isaiah 57

Èmi yóò ṣí òdodo yín páyà àti iṣẹ́ yín, wọn kì yóò sì ṣe yín ní àǹfààní.

Isaiah 57:12 (UKJV) I will declare your righteousness, and your works; for they shall not profit you.

10Àwọn ọ̀nà yín gbogbo ti mú àárẹ̀ ba á yín, ṣùgbọ́n ẹ kò ní sọ pé, ‘Kò sí ìrètí mọ́?’ Ẹ rí okun kún agbára yín, nípa bẹ́ẹ̀ òòyì kò kọ́ ọ yín.

11“Ta ni ó ń pá yín láyà tí ń bà yín lẹ́rù tí ẹ fi ń ṣèké sí mi, àti tí ẹ̀yin kò fi rántí mi tàbí kí ẹ rò yí nínú ọkàn yín? Ǹjẹ́ kì í ṣe nítorí dídákẹ́ jẹ́ẹ́ mi fún ìgbà pípẹ́ tí ẹ̀yin kò fi bẹ̀rù mi?

12Èmi yóò ṣí òdodo yín páyà àti iṣẹ́ yín, wọn kì yóò sì ṣe yín ní àǹfààní.

13Nígbà tí ẹ bá kígbe fún ìrànlọ́wọ́ ẹ jẹ́ kí àkójọ àwọn ère yín gbà yín! Atẹ́gùn yóò gbá gbogbo wọn lọ, èémí lásán làsàn ni yóò gbá wọn lọ. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá fi mí ṣe ààbò rẹ̀ ni yóò jogún ilẹ̀ náà yóò sì jogún òkè mímọ́ mi.”

14A ó sì sọ wí pé: “Tún mọ, tún mọ, tún ọ̀nà náà ṣe! Ẹ mú àwọn ohun ìkọ̀sẹ̀ kúrò ní ọ̀nà àwọn ènìyàn mi.”

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.