6Àwọn ère tí ó wà ní àárín òkúta dídán wọ́n n nì, nínú kòtò jíjìn ni ìpín in yín; àwọ̀n ni ìpín in yín. Bẹ́ẹ̀ ni, sí wọn ni ẹ ti ta ọrẹ ohun mímu yín sílẹ̀ àti láti ta ọrẹ ìyẹ̀fun. Nítorí àwọn nǹkan wọ̀nyí, ǹjẹ́ ó yẹ kí n dáwọ́ dúró?
7Ìwọ ti ṣe ibùsùn rẹ lórí òkè gíga tí ó rẹwà; níbẹ̀ ni ẹ lọ láti lọ ṣe ìrúbọ yín.
8Lẹ́yìn àwọn ìlẹ̀kùn yín àti òpó ìlẹ̀kùn yín níbẹ̀ ni ẹ fi àwọn àmì òrìṣà yín sí. Ní kíkọ̀ mí sílẹ̀, ẹ ṣí ibùsùn yín sílẹ̀, ẹ gun orí rẹ̀ lọ, ẹ sì ṣí i sílẹ̀ gbagada; ẹ ṣe àdéhùn pẹ̀lú àwọn tí ẹ fẹ́ràn ibùsùn wọn, ẹ̀yin sì ń wo ìhòhò wọn.
9Ẹ̀yin lọ sí Moleki pẹ̀lú òróró olifi ẹ sì fi kún òórùn dídùn yín. Ẹ rán ikọ̀ yín lọ jìnnà réré; ẹ sọ̀kalẹ̀ sí ibojì pẹ̀lú!
10Àwọn ọ̀nà yín gbogbo ti mú àárẹ̀ ba á yín, ṣùgbọ́n ẹ kò ní sọ pé, ‘Kò sí ìrètí mọ́?’ Ẹ rí okun kún agbára yín, nípa bẹ́ẹ̀ òòyì kò kọ́ ọ yín.