Isaiah 60

“Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a ti kórìíra rẹ, a sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀, láìsí ẹnìkan tí ó ń gba ọ̀dọ̀ rẹ kọjá, Èmi yóò ṣe ọ́ ní ìṣògo ayérayé àti ayọ̀ àtìrandíran.

Isaiah 60:15 (UKJV) Whereas you has been forsaken and hated, so that no man went through you, I will make you an eternal excellency, a joy of many generations.

13“Ògo Lebanoni yóò wá sí ọ̀dọ̀ rẹ, igi junifa, firi àti sípírẹ́ṣì papọ̀, láti bu ọlá fún ilé ìsìn mi; àti pé èmi yóò sì ṣe ibi ẹsẹ̀ mi lógo.

14Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin àwọn apọ́nilójú rẹ yóò wá foríbalẹ̀ fún ọ; gbogbo àwọn tí ó ti kẹ́gàn rẹ ni wọn yóò tẹríba níwájú rẹ wọn yóò sì pè ọ́ ní ìlú Olúwa, Sioni ti Ẹni Mímọ́ Israẹli.

15“Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a ti kórìíra rẹ, a sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀, láìsí ẹnìkan tí ó ń gba ọ̀dọ̀ rẹ kọjá, Èmi yóò ṣe ọ́ ní ìṣògo ayérayé àti ayọ̀ àtìrandíran.

16Ìwọ yóò mu wàrà gbogbo orílẹ̀-èdè a ó sì fun ọ́ ni ọmú àwọn ọba. Nígbà náà ni ìwọ yóò mọ̀ pé, Èmi Olúwa, èmi ni Olùgbàlà rẹ, Olùdáǹdè rẹ, Alágbára ti Jakọbu.

17Dípò idẹ, èmi ó mú wúrà wá fún ọ, dípò fàdákà èmi ó mú irin wá. Dípò igi yóò mú idẹ wá fún ọ, àti irin dípò òkúta. Èmi yóò fi àlàáfíà ṣe àwọn ìjòyè rẹ àti òdodo gẹ́gẹ́ bí alákòóso rẹ.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.