Isaiah 9

Olúwa ti dojú iṣẹ́ kan kọ Jakọbu; yóò sì wá sórí Israẹli.

Isaiah 9:8 (UKJV) The Lord sent a word into Jacob, and it has lighted upon Israel.

6Nítorí a bí ọmọ kan fún wa, a fi ọmọkùnrin kan fún wa, ìjọba yóò sì wà ní èjìká rẹ̀. A ó sì máa pè é ní Ìyanu Olùdámọ̀ràn, Ọlọ́run Alágbára, Baba ayérayé, Ọmọ ọba aládé Àlàáfíà.

7Ní ti gbígbòòrò Ìjọba rẹ̀ àti àlàáfíà rẹ̀ ni kì yóò ní ìpẹ̀kun. Yóò jẹ ọba lórí ìtẹ́ Dafidi àti lórí ẹ̀kún un rẹ̀ gbogbo, nípa ìfìdímúlẹ̀ àti ìgbéró rẹ̀, pẹ̀lú òtítọ́ àti òdodo láti ìgbà náà lọ àti títí láéláé. Ìtara Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni yóò mú èyí ṣẹ.

8Olúwa ti dojú iṣẹ́ kan kọ Jakọbu; yóò sì wá sórí Israẹli.

9Gbogbo ènìyàn ni yóò sì mọ̀ ọ́n— Efraimu àti gbogbo olùgbé Samaria— tí ó sọ pẹ̀lú ìgbéraga àti gààrù àyà pé.

10Àwọn bíríkì ti wó lulẹ̀ ṣùgbọ́n a ó tún un kọ́ pẹ̀lú òkúta dídán, a ti gé àwọn igi sikamore lulẹ̀ ṣùgbọ́n igi kedari ní a ó fi dípò wọn.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.