Jeremiah 17

Kódà àwọn ọmọ wọn rántí pẹpẹ àti ère Aṣerah lẹ́bàá igi tí ó tẹ́ rẹrẹ àti àwọn òkè gíga.

Jeremiah 17:2 (UKJV) Whilst their children remember their altars and their groves by the green trees upon the high hills.

1“Ẹ̀ṣẹ̀ Juda ni a fi kálámù irin kọ, èyí tí a fi ṣóńṣó òkúta adamante gbẹ́ ẹ, sórí wàláà oókan àyà wọn, àti sórí ìwo pẹpẹ yín.

2Kódà àwọn ọmọ wọn rántí pẹpẹ àti ère Aṣerah lẹ́bàá igi tí ó tẹ́ rẹrẹ àti àwọn òkè gíga.

3Àwọn òkè nínú ilẹ̀ àti àwọn ọrọ̀ rẹ̀ àti ọlá rẹ̀ ni èmi yóò fi sílẹ̀ bí ìjẹ pẹ̀lú àwọn ibi gíga, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó pọ̀ káàkiri orílẹ̀-èdè yín.

4Láti ipasẹ̀ àìṣedéédéé yín ni ẹ̀yin yóò ti sọ ogún tí mo fún un yín nù. Èmi yóò fi yín fún ọ̀tá yín bí ẹrú ní ilẹ̀ tí ẹ̀yin kò mọ̀, nítorí ẹ̀yin ti mú inú bí mi, èyí tí yóò sì wà títí ayé.”

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.