Jeremiah 2

Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ̀ mí wá wí pé:

Jeremiah 2:1 (UKJV) Moreover the word of the LORD came to me, saying,

1Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ̀ mí wá wí pé:

2“Lọ kí o sì kéde sí etí Jerusalẹmu pé: “Báyìí ni Olúwa wí, “ ‘Èmi rántí ìṣeun ìgbà èwe rẹ, ìfẹ́ ìgbéyàwó rẹ àti nígbà tí ìwọ tẹ̀lé mi nínú ijù, nínú ìyàngbẹ ilẹ̀.

3Israẹli jẹ́ mímọ́ sí Olúwa, àkọ́kọ́ èso ìkórè rẹ̀, gbogbo ẹnikẹ́ni tí ó jẹ run ni a ó dá lẹ́bi, ibi yóò sì wá sí orí wọn,’ ” bẹ́ẹ̀ ni Olúwa wí.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.