Jeremiah 23

“Nítorí náà, ọ̀nà wọn yóò di yíyọ́, a ó lé wọn jáde sínú òkùnkùn; níbẹ̀ ni wọn yóò ṣubú. Èmi yóò mú ìdààmú wá sórí wọn, ní ọdún tí a jẹ wọ́n ní ìyà,” ni Olúwa wí.

Jeremiah 23:12 (UKJV) Wherefore their way shall be unto them as slippery ways in the darkness: they shall be driven on, and fall therein: for I will bring evil upon them, even the year of their visitation, says the LORD.

10Ilẹ̀ náà kún fún panṣágà ènìyàn; nítorí ègún, ilẹ̀ náà gbẹ, àwọn koríko orí aṣálẹ̀ ilẹ̀ náà rọ. Àwọn wòlíì tẹ̀lé ọ̀nà búburú, wọ́n sì ń lo agbára wọn lọ́nà àìtọ́.

11“Wòlíì àti àlùfáà kò gbé ìgbé ayé ìwà-bí-Ọlọ́run; kódà nínú tẹmpili mi ni mo rí ìwà búburú wọn,” ni Olúwa wí.

12“Nítorí náà, ọ̀nà wọn yóò di yíyọ́, a ó lé wọn jáde sínú òkùnkùn; níbẹ̀ ni wọn yóò ṣubú. Èmi yóò mú ìdààmú wá sórí wọn, ní ọdún tí a jẹ wọ́n ní ìyà,” ni Olúwa wí.

13“Láàrín àwọn wòlíì Samaria, Èmi rí ohun tí ń lé ni sá. Wọ́n sọ àsọtẹ́lẹ̀ lórúkọ Baali wọ́n sì mú Israẹli ènìyàn mi ṣìnà.

14Àti láàrín àwọn wòlíì Jerusalẹmu, èmi ti rí ohun búburú. Wọ́n ṣe panṣágà, wọ́n sì ń ṣèké. Wọ́n fún àwọn olùṣe búburú ní agbára, tó bẹ́ẹ̀ tí kò sí ẹnìkan tí ó yípadà kúrò nínú ìwà búburú rẹ̀. Gbogbo wọn dàbí Sodomu níwájú mi, àti àwọn ènìyàn olùgbé rẹ̀ bí Gomorra.”

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.