Jeremiah 30

“ ‘Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ṣe yín ní ibi ni ibi yóò bá, àní gbogbo àwọn ọ̀tá yín ni a ó sọ di àtìpó ní ilẹ̀ àjèjì; gbogbo àwọn tí wọ́n bà yín jẹ́ ni a ó bàjẹ́.

Jeremiah 30:16 (UKJV) Therefore all they that devour you shall be devoured; and all yours adversaries, every one of them, shall go into captivity; and they that spoil you shall be a spoil, and all that prey upon you will I give for a prey.

14Gbogbo àwọn olùfẹ́ rẹ ti gbàgbé rẹ, wọn kò sì náání rẹ mọ́ pẹ̀lú. Mo ti nà ọ gẹ́gẹ́ bí ọ̀tá rẹ yóò ti nà ọ, mo sì bá a ọ wí gẹ́gẹ́ bí ìkà, nítorí tí ẹ̀bi rẹ pọ̀ púpọ̀, ẹ̀ṣẹ̀ rẹ kò sì lóǹkà.

15Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń kígbe nítorí ọgbẹ́ yín, ìrora yín èyí tí kò ní oògùn? Nítorí ọ̀pọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ yín àti ẹ̀bi yín tó ga ni mo fi ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí sí i yín.

16“ ‘Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ṣe yín ní ibi ni ibi yóò bá, àní gbogbo àwọn ọ̀tá yín ni a ó sọ di àtìpó ní ilẹ̀ àjèjì; gbogbo àwọn tí wọ́n bà yín jẹ́ ni a ó bàjẹ́.

17Ṣùgbọ́n èmi yóò fi ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìlera fún yín, èmi yóò sì wo ọ̀gbẹ́ yín sàn,’ ni Olúwa wí, ‘nítorí tí a pè yín ní alárìnkiri, Sioni tí gbogbo ènìyàn dágunlá sí.’

18“Èyí ni ohun tí Olúwa wí: “ ‘Èmi yóò dá gbogbo ìre àgọ́ Jakọbu padà, èmi yóò sì ṣe àánú fún olùgbé àgọ́ rẹ̀; ìlú náà yóò sì di títúnṣe tí ààfin ìlú náà yóò sì wà ní ipò rẹ̀.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.