Jeremiah 4

Fi àmì láti sálọ sí Sioni hàn, sálọ fún ààbò láìsí ìdádúró. Nítorí èmi ó mú àjálù láti àríwá wá, àní ìparun tí ó burú jọjọ.”

Jeremiah 4:6 (UKJV) Set up the standard toward Zion: retire, stay not: for I will bring evil from the north, and a great destruction.

4Kọ ara rẹ ní ilà sí Olúwa, kọ ọkàn rẹ ní ilà, ẹ̀yin ènìyàn Juda àti gbogbo ènìyàn Jerusalẹmu, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ìbínú mi yóò ru jáde yóò sì jó bí iná, nítorí ibi tí o ti ṣe kì yóò sí ẹni tí yóò pa á.

5“Kéde ní Juda, kí o sì polongo ní Jerusalẹmu, kí o sì wí pé: ‘Fun fèrè káàkiri gbogbo ilẹ̀!’ Kí o sì kígbe: ‘Kó ara jọ pọ̀! Jẹ́ kí a sálọ sí ìlú olódi.’

6Fi àmì láti sálọ sí Sioni hàn, sálọ fún ààbò láìsí ìdádúró. Nítorí èmi ó mú àjálù láti àríwá wá, àní ìparun tí ó burú jọjọ.”

7Kìnnìún ti sá jáde láti inú ibùgbé rẹ̀, apanirun orílẹ̀-èdè sì ti jáde. Ó ti fi ààyè rẹ̀ sílẹ̀ láti ba ilẹ̀ rẹ̀ jẹ́. Ìlú rẹ yóò di ahoro láìsí olùgbé.

8Nítorí náà, gbé aṣọ ọ̀fọ̀ wọ̀ káàánú kí o sì pohùnréré ẹkún, nítorí ìbínú ńlá Olúwa kò tí ì kúrò lórí wa.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.