Jeremiah 40

Ṣùgbọ́n Gedaliah ọmọ Ahikamu sọ fún Johanani ọmọ Karea pé, “Má ṣe ṣe nǹkan yìí! Nítorí nǹkan tí ò ń sọ nípa Iṣmaeli kì í ṣe òtítọ́.”

Jeremiah 40:16 (UKJV) But Gedaliah the son of Ahikam said unto Johanan the son of Kareah, You shall not do this thing: for you speak falsely of Ishmael.

14Wọ́n sì sọ fún un wí pé, “Ǹjẹ́ ìwọ ha mọ̀ pé Baalisi ọba àwọn Ammoni ti rán Iṣmaeli ọmọkùnrin Netaniah láti lọ mú ẹ̀mí rẹ?” Ṣùgbọ́n Gedaliah ọmọkùnrin ti Ahikamu kò gbà wọ́n gbọ́.

15Nígbà náà ni Johanani ọmọkùnrin Karea sọ ní ìkọ̀kọ̀ fún Gedaliah ní Mispa pé, “Jẹ́ kí èmi lọ pa Iṣmaeli ọmọkùnrin Netaniah, ẹnikẹ́ni kò sì ní mọ èyí. Kí ni ìdí rẹ̀ tí yóò ṣe mú ẹ̀mí rẹ, tí o sì ṣe fẹ́ mú àwọn Júù tí ó yí ọ ká túká, kí ìyókù Juda sì parun?”

16Ṣùgbọ́n Gedaliah ọmọ Ahikamu sọ fún Johanani ọmọ Karea pé, “Má ṣe ṣe nǹkan yìí! Nítorí nǹkan tí ò ń sọ nípa Iṣmaeli kì í ṣe òtítọ́.”

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.