Jeremiah 46

Má bẹ̀rù, Jakọbu ìránṣẹ́ mi, nítorí pé mo wà pẹ̀lú rẹ,” bẹ́ẹ̀ ni Olúwa wí. “Bí mo tilẹ̀ pa gbogbo orílẹ̀-èdè run, láàrín àwọn tí mo fọ́n yín ká sí. Èmi kò ní run yín tán. Èmi yóò jẹ ọ́ ní ìyà lórí òdodo, èmi kí yóò jọ̀wọ́ rẹ lọ́wọ́ lọ láìjẹ ọ́ ní yà.”

Jeremiah 46:28 (UKJV) Fear you not, O Jacob my servant, says the LORD: for I am with you; for I will make a full end of all the nations where I have driven you: but I will not make a full end of you, but correct you in measure; yet will I not leave you wholly unpunished.

26Èmi ó sì fi wọ́n lé àwọn tó wá ẹ̀mí wọn lọ́wọ́, lé Nebukadnessari ọba Babeli, ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, Ejibiti yóò sì di gbígbé bí i ti àtijọ́,” ni Olúwa wí.

27“Má bẹ̀rù, ìwọ Jakọbu ìránṣẹ́ mi, má fòyà, ìwọ Israẹli. Dájúdájú èmi ó gbà ọ́ láti ọ̀nà jíjìn, àwọn ọmọ ọmọ rẹ ní ilẹ̀ ìgbèkùn. Jakọbu yóò tún ní àlàáfíà àti ààbò, kò sì ṣí ẹni tí yóò dẹ́rùbà á.

28Má bẹ̀rù, Jakọbu ìránṣẹ́ mi, nítorí pé mo wà pẹ̀lú rẹ,” bẹ́ẹ̀ ni Olúwa wí. “Bí mo tilẹ̀ pa gbogbo orílẹ̀-èdè run, láàrín àwọn tí mo fọ́n yín ká sí. Èmi kò ní run yín tán. Èmi yóò jẹ ọ́ ní ìyà lórí òdodo, èmi kí yóò jọ̀wọ́ rẹ lọ́wọ́ lọ láìjẹ ọ́ ní yà.”

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.