Jeremiah 5

Olúwa, ojú rẹ kò ha wà lára òtítọ́? Ìwọ lù wọ́n, kò dùn wọ́n; ìwọ bá wọn wí, wọ́n kọ̀ láti yípadà. Wọ́n mú ojú wọn le ju òkúta lọ, wọ́n sì kọ̀ láti yípadà.

Jeremiah 5:3 (UKJV) O LORD, are not yours eyes upon the truth? you have stricken them, but they have not grieved; you have consumed them, but they have refused to receive correction: they have made their faces harder than a rock; they have refused to return.

1“Lọ sókè àti sódò àwọn òpópó Jerusalẹmu, wò yíká, kí o sì mọ̀, kí o sì wá kiri. Bí o bá le è rí ẹnìkan, tí ó jẹ́ olóòtítọ́ àti olódodo, n ó dáríjì ìlú yìí.

2Bí wọ́n tilẹ̀ wí pé, ‘Bí Olúwa ti ń bẹ,’ síbẹ̀ wọ́n búra èké.”

3Olúwa, ojú rẹ kò ha wà lára òtítọ́? Ìwọ lù wọ́n, kò dùn wọ́n; ìwọ bá wọn wí, wọ́n kọ̀ láti yípadà. Wọ́n mú ojú wọn le ju òkúta lọ, wọ́n sì kọ̀ láti yípadà.

4Èmi sì rò pé, “Tálákà ni àwọn yìí; wọn jẹ́ aṣiwèrè, nítorí pé wọn kò mọ ọ̀nà Olúwa, àti ohun tí Ọlọ́run wọn ń fẹ́.

5Nítorí náà, èmi yóò tọ àwọn adarí lọ, n ó sì bá wọn sọ̀rọ̀; ó dájú wí pé wọ́n mọ ọ̀nà Olúwa àti ohun tí Ọlọ́run wọn ń fẹ́.” Ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìfìmọ̀ṣọ̀kan, wọ́n ti ba àjàgà jẹ́, wọ́n sì ti já ìdè.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.