9Nítorí pé èmi yóò ru, bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò gbé sókè sí Babeli àwọn orílẹ̀-èdè ńlá láti ilẹ̀ àríwá. Wọn yóò gba àyà wọn lẹ́gbẹ́ rẹ̀; láti àríwá wá, à ó sì mú ọ. Ọfà wọn yóò dàbí ọfà àwọn akọni akíkanjú tí wọn kì í wà lọ́wọ́ òfo.
10A ó dààmú Babeli, gbogbo àwọn tó dààmú rẹ yóò sì mú ìfẹ́ wọn ṣẹ,” ni Olúwa wí.
11“Nítorí pé inú yín dùn nítorí pé ẹ̀yìn yọ̀, ẹ̀yìn olè tí ó jí ìní mi, nítorí tí ẹ̀yìn fi ayọ̀ fò bí ẹgbọrọ abo màlúù sí koríko tútù, ẹ sì ń yan bí akọ ẹṣin.
12Ojú yóò ti ìyá rẹ, ẹni tí ó bí ọ yóò sì gba ìtìjú. Òun ni yóò jẹ́ kékeré jù nínú àwọn orílẹ̀-èdè, ilẹ̀ aṣálẹ̀ àti aginjù tí kò lọ́ràá.
13Nítorí ìbínú Olúwa, kì yóò ní olùgbé; ẹnikẹ́ni kò sì ní gbé inú rẹ̀. Gbogbo àwọn tí ó bá kọjá ni Babeli yóò fi ṣe yẹ̀yẹ́ nítorí ọgbẹ́ rẹ̀.