Jeremiah 50

“Ní ọjọ́ wọ̀nyí àti ní àkókò náà,” ni Olúwa wí, “Àwọn ọmọ Israẹli yóò jùmọ̀ wá, àwọn, àti àwọn ọmọ Juda, wọn yóò lọ pẹ̀lú ẹkún láti ṣàfẹ́rí Olúwa Ọlọ́run wọn.

Jeremiah 50:4 (UKJV) In those days, and in that time, says the LORD, the children of Israel shall come, they and the children of Judah together, going and weeping: they shall go, and seek the LORD their God.

2“Ẹ sọ ọ́ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, ẹ sì kéde, kí ẹ sì gbé àsíá sókè, ẹ kéde rẹ̀ ẹ má sì ṣe bò ó, wí pé, ‘A kó Babeli, ojú tí Beli, a fọ́ Merodaki túútúú, ojú ti àwọn ère rẹ̀, a fọ́ àwọn òrìṣà rẹ̀ túútúú.’

3Àwọn ìlú ní apá àríwá yóò sì máa gbóguntì wọ́n. Gbogbo àwọn ènìyàn àti ẹranko ni yóò sá kúrò ní ìlú yìí.

4“Ní ọjọ́ wọ̀nyí àti ní àkókò náà,” ni Olúwa wí, “Àwọn ọmọ Israẹli yóò jùmọ̀ wá, àwọn, àti àwọn ọmọ Juda, wọn yóò lọ pẹ̀lú ẹkún láti ṣàfẹ́rí Olúwa Ọlọ́run wọn.

5Wọn ó máa béèrè ọ̀nà Sioni, ojú wọn yóò sì yí síhà ibẹ̀, wí pé ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a darapọ̀ mọ́ Olúwa ní májẹ̀mú ayérayé, tí a kì yóò gbàgbé.

6“Àwọn ènìyàn mi ti jẹ́ àgùntàn tí ó sọnù, àwọn olùṣọ́-àgùntàn wọn ti jẹ́ kí wọn ṣìnà, wọ́n ti jẹ́ kí wọn rìn lórí òkè wọ́n ti lọ láti orí òkè ńlá dé òkè kékeré, wọn ti gbàgbé ibùsùn wọn.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.