Jeremiah 50

Wọn ó máa béèrè ọ̀nà Sioni, ojú wọn yóò sì yí síhà ibẹ̀, wí pé ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a darapọ̀ mọ́ Olúwa ní májẹ̀mú ayérayé, tí a kì yóò gbàgbé.

Jeremiah 50:5 (UKJV) They shall ask the way to Zion with their faces in that direction, saying, Come, and let us join ourselves to the LORD in a perpetual covenant that shall not be forgotten.

3Àwọn ìlú ní apá àríwá yóò sì máa gbóguntì wọ́n. Gbogbo àwọn ènìyàn àti ẹranko ni yóò sá kúrò ní ìlú yìí.

4“Ní ọjọ́ wọ̀nyí àti ní àkókò náà,” ni Olúwa wí, “Àwọn ọmọ Israẹli yóò jùmọ̀ wá, àwọn, àti àwọn ọmọ Juda, wọn yóò lọ pẹ̀lú ẹkún láti ṣàfẹ́rí Olúwa Ọlọ́run wọn.

5Wọn ó máa béèrè ọ̀nà Sioni, ojú wọn yóò sì yí síhà ibẹ̀, wí pé ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a darapọ̀ mọ́ Olúwa ní májẹ̀mú ayérayé, tí a kì yóò gbàgbé.

6“Àwọn ènìyàn mi ti jẹ́ àgùntàn tí ó sọnù, àwọn olùṣọ́-àgùntàn wọn ti jẹ́ kí wọn ṣìnà, wọ́n ti jẹ́ kí wọn rìn lórí òkè wọ́n ti lọ láti orí òkè ńlá dé òkè kékeré, wọn ti gbàgbé ibùsùn wọn.

7Gbogbo àwọn tí ó rí wọn, ti pa wọ́n jẹ àwọn ọ̀tá wọ́n sì wí pé, ‘Àwa kò jẹ̀bi nítorí pé wọ́n ti ṣẹ̀ sí Olúwa ibùgbé òdodo àti ìrètí àwọn baba wọn.’

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.