18Asán ni wọ́n, àti iṣẹ́ ìsìnà, nígbà ìbẹ̀wò wọn, wọn ó ṣègbé.
19Ẹni tí ó jẹ́ ìpín Jakọbu kó rí bí ìwọ̀nyí; nítorí òun ni ó dá ohun gbogbo, àti gbogbo àwọn ẹ̀yà ajogún, Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀.
20“Ìwọ ni kùmọ̀ ogun ohun èlò ogun mi, ohun èlò ìjà mi, pẹ̀lú rẹ èmi ó fọ́ orílẹ̀-èdè túútúú, èmi ó bà àwọn ilé ọba jẹ́.
21Pẹ̀lú rẹ, èmi ó pa ẹṣin àti ẹni tí ó gùn ún pẹ̀lú rẹ̀; èmi ó ba kẹ̀kẹ́ ogun jẹ́ pẹ̀lú èmi ó pa awakọ̀,
22pẹ̀lú rẹ, mo pa ọkùnrin àti obìnrin, pẹ̀lú rẹ, mo pa àgbàlagbà àti ọmọdé, pẹ̀lú rẹ, mo pa ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin.