Jeremiah 51

“Mo lòdì sí ọ, ìwọ òkè apanirun ìwọ ti ba gbogbo ayé jẹ́,” ni Olúwa wí. “Èmi ó na ọwọ́ mi sí ọ, èmi yóò yí ọ kúrò lórí àpáta, Èmi yóò sọ ọ́ dàbí òkè tí a ti jó.

Jeremiah 51:25 (UKJV) Behold, I am against you, O destroying mountain, says the LORD, which destroys all the earth: and I will stretch out mine hand upon you, and roll you down from the rocks, and will make you a burnt mountain.

23Èmi yóò sì fi ọ́ fọ́ olùṣọ́-àgùntàn, àti agbo àgùntàn rẹ̀ túútúú, èmi yóò sì fi ọ́ fọ́ àgbẹ̀ àti àjàgà màlúù túútúú, èmi yóò sì fi ọ́ fọ́ baálẹ̀ àti àwọn ìjòyè rẹ̀ túútúú.

24“Ní ojú rẹ, èmi yóò san án fún Babeli àti gbogbo àwọn olùgbé inú rẹ̀ fún gbogbo ibi tí wọ́n ti ṣe ní Sioni,” ni Olúwa wí.

25“Mo lòdì sí ọ, ìwọ òkè apanirun ìwọ ti ba gbogbo ayé jẹ́,” ni Olúwa wí. “Èmi ó na ọwọ́ mi sí ọ, èmi yóò yí ọ kúrò lórí àpáta, Èmi yóò sọ ọ́ dàbí òkè tí a ti jó.

26A kò ní mú òkúta kankan láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ lò gẹ́gẹ́ bí igun ilé tàbí fún ìpínlẹ̀ nítorí pé ìwọ yóò di ahoro títí ayé,” ní Olúwa wí.

27“Gbé àsíá sókè ní ilẹ̀ náà! Fọn ìpè láàrín àwọn orílẹ̀-èdè! Sọ àwọn orílẹ̀-èdè di mímọ́ sórí rẹ̀, pe àwọn ìjọba yìí láti dojúkọ ọ́: Ararati, Minini àti Aṣkenasi. Yan olùdarí ogun láti kọlù ú, rán àwọn ẹṣin sí i bí ọ̀pọ̀ eṣú.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.