Jeremiah 6

Gẹ́gẹ́ bí kànga ṣe ń da omi inú rẹ̀ sílẹ̀, náà ni ó ń tú ìwà búburú rẹ̀ jáde. Ìwà ipá àti ìparun ń tún pariwo nínú rẹ̀; nígbà gbogbo ni àìsàn àti ọgbẹ́ rẹ̀ ń wà níwájú mi.

Jeremiah 6:7 (UKJV) As a fountain casts out her waters, so she casts out her wickedness: violence and spoil is heard in her; before me continually is grief and wounds.

5Nítorí náà, ẹ dìde, ẹ jẹ́ kí a kọlù ú ní àṣálẹ́ kí a sì ba odi alágbára rẹ̀ jẹ́.”

6Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Àwọn ọmọ-ogun wí: “Ẹ ké àwọn igi náà lulẹ̀ kí ẹ sì mọ odi ààbò yí Jerusalẹmu ká. Èyí ni ìlú títóbi tí a ó bẹ̀wò, nítorí pé ó kún fún ìninilára.

7Gẹ́gẹ́ bí kànga ṣe ń da omi inú rẹ̀ sílẹ̀, náà ni ó ń tú ìwà búburú rẹ̀ jáde. Ìwà ipá àti ìparun ń tún pariwo nínú rẹ̀; nígbà gbogbo ni àìsàn àti ọgbẹ́ rẹ̀ ń wà níwájú mi.

8Ìwọ Jerusalẹmu, gba ìkìlọ̀, kí Èmi kí ó má ba à lọ kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ, kí n sì sọ ilẹ̀ rẹ di ahoro, tí kò ní ní olùgbé.”

9Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: “Jẹ́ kí wọn pèsè ìyókù Israẹli ní tónítóní bí àjàrà; na ọwọ́ rẹ sí àwọn ẹ̀ka nì lẹ́ẹ̀kan sí i gẹ́gẹ́ bí ẹnìkan ti í kó èso àjàrà jọ.”

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.