Jeremiah 8

Níwọ́n ìgbà tí a pa àwọn ènìyàn mi run, èmi náà run pẹ̀lú, èmi ṣọ̀fọ̀, ìrora sì mú mi káká.

Jeremiah 8:21 (UKJV) For the hurt of the daughter of my people am I hurt; I am black; astonishment has taken hold on me.

19Fetí sí ẹkún àwọn ènìyàn mi láti ilẹ̀ jíjìnnà wá: “Olúwa kò ha sí ní Sioni bí? Ọba rẹ̀ kò sí níbẹ̀ mọ́ ni?” “Èéṣe tí wọ́n fi mú mi bínú pẹ̀lú ère wọn, pẹ̀lú àwọn òrìṣà àjèjì tí wọn kò níláárí?”

20“Ìkórè ti rékọjá, ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn ti parí, síbẹ̀ a kò gbà wá là.”

21Níwọ́n ìgbà tí a pa àwọn ènìyàn mi run, èmi náà run pẹ̀lú, èmi ṣọ̀fọ̀, ìrora sì mú mi káká.

22Kò ha sí ìkunra ní Gileadi bí? Kò ha sí àwọn oníṣègùn níbẹ̀? Kí ló ha dé tí kò fi sí ìwòsàn fún ọgbẹ́ àwọn ènìyàn mi?

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.