4Ṣùgbọ́n ìwọ ṣá ìbẹ̀rù tì, ìwọ sì dí iṣẹ́ ìsìn lọ́nà níwájú Ọlọ́run.
5Nítorí pé ẹnu ara rẹ̀ ni ó jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ìwọ sì yàn ahọ́n alárékérekè ni ààyò.
6Ẹnu ara rẹ̀ ni ó dá lẹ́bi, kì í ṣe èmi; àní ètè ara rẹ̀ ni ó jẹ́rìí gbè ọ́.
7“Ìwọ ha í ṣe ọkùnrin tí a kọ́ bí? Tàbí a ha dá ọ ṣáájú àwọn òkè?
8Ìwọ gbúròó àṣírí Ọlọ́run rí? Tàbí ìwọ ha dá ọgbọ́n dúró sọ́dọ̀ ara rẹ?