2“Èmi ti gbọ́ irú ohun púpọ̀ bẹ́ẹ̀ rí ayọnilẹ́nu onítùnú ènìyàn ní gbogbo yín.
3Ọ̀rọ̀ asán lè ni òpin? Tàbí kí ni ó gbó ọ láyà tí ìwọ fi dáhùn?
4Èmi pẹ̀lú le sọ bí ẹ̀yin; bí ọkàn yín bá wà ní ipò ọkàn mi, èmi le sọ ọ̀rọ̀ dáradára púpọ̀ sí yín ní ọrùn, èmi a sì mi orí mi sí i yín.
5Èmi ìbá fi ọ̀rọ̀ ẹnu mi gbà yín ni ìyànjú, àti ṣíṣí ètè mi ìbá sì tu ìbìnújẹ́ yín.
6“Bí èmi tilẹ̀ sọ̀rọ̀, ìbìnújẹ́ mi kò lọ; bí mo sì tilẹ̀ dákẹ́, níbo ni ìtùnú mí ko kúrò?