5Èmi ìbá fi ọ̀rọ̀ ẹnu mi gbà yín ni ìyànjú, àti ṣíṣí ètè mi ìbá sì tu ìbìnújẹ́ yín.
6“Bí èmi tilẹ̀ sọ̀rọ̀, ìbìnújẹ́ mi kò lọ; bí mo sì tilẹ̀ dákẹ́, níbo ni ìtùnú mí ko kúrò?
7Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ó dá mi lágara; ìwọ Ọlọ́run mú gbogbo ẹgbẹ́ mi takété.
8Ìwọ fi ìhunjọ kùn mí lára, èyí tí o jẹ́rìí tì mí; àti rírù tí ó hàn lára mi, ó jẹ́rìí tì mí ní ojú.
9Ọlọ́run fi i ìbínú rẹ̀ fà mí ya, ó sì gbóguntì mí; ó pa eyín rẹ̀ keke sí mi, ọ̀tá mi sì gbójú rẹ̀ sí mi.