Jobu 18

Ìrìn ẹsẹ̀ agbára rẹ̀ yóò di fífọ; ète òun tìkára rẹ̀ ni yóò bí i ṣubú.

Job 18:7 (UKJV) The steps of his strength shall be straitened, and his own counsel shall cast him down.

5“Nítòótọ́ ìmọ́lẹ̀ ènìyàn búburú ni a ó pa kúrò, ọ̀wọ́-iná rẹ̀ kì yóò sì tan ìmọ́lẹ̀.

6Ìmọ́lẹ̀ yóò di òkùnkùn nínú àgọ́ rẹ̀, fìtílà ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ ni a ó sì pa pẹ̀lú.

7Ìrìn ẹsẹ̀ agbára rẹ̀ yóò di fífọ; ète òun tìkára rẹ̀ ni yóò bí i ṣubú.

8Nípa ẹ̀ṣẹ̀ òun tìkára rẹ̀ ó ti bọ́ sínú àwọ̀n, ó sì rìn lórí okùn dídẹ.

9Tàkúté ni yóò mú un ní gìgísẹ̀, àwọn àwọ̀n tí a dẹ yóò sì ṣẹ́gun rẹ̀.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.