7ṣùgbọ́n yóò ṣègbé láéláé bí ìgbẹ́ ara rẹ̀; àwọn tí ó ti rí i rí yóò wí pé, ‘Òun ha dà?’
8Yóò fò lọ bí àlá, a kì yóò sì rí i, àní a ó lé e lọ bi ìran òru.
9Ojú tí ó ti rí i rí kì yóò sì rí i mọ́, bẹ́ẹ̀ ni ibùjókòó rẹ̀ kì yóò sì ri i mọ́.
10Àwọn ọmọ rẹ̀ yóò máa wá àti rí ojúrere lọ́dọ̀ tálákà, ọwọ́ rẹ̀ yóò sì kó ọrọ̀ wọn padà.
11Egungun rẹ̀ kún fún agbára ìgbà èwe rẹ̀, tí yóò bá a dùbúlẹ̀ nínú erùpẹ̀.