Jobu 21

Ẹ jọ̀wọ́ mi ki èmi sọ̀rọ̀; lẹ́yìn ìgbà ìwọ le máa fi mi ṣẹ̀sín ń ṣo.

Job 21:3 (UKJV) Suffer me that I may speak; and after that I have spoken, mock on.

1Jobu wá dáhùn, ó sì wí pé,

2“Ẹ tẹ́tí sílẹ̀ dáradára sì àwọn ọ̀rọ̀ mi, kí èyí kí ó jásí ìtùnú fún mi.

3Ẹ jọ̀wọ́ mi ki èmi sọ̀rọ̀; lẹ́yìn ìgbà ìwọ le máa fi mi ṣẹ̀sín ń ṣo.

4“Àròyé mi ha ṣe sí ènìyàn bí? Èétise tí ọkàn mi kì yóò fi ṣe àìbalẹ̀?

5Ẹ wò mí fín, kí ẹnu kí ó sì yà yín, kí ẹ sì fi ọwọ́ lé ẹnu yín.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.