7Nítorí kí ní ènìyàn búburú fi wà ní ayé, tí wọ́n gbó, àní tí wọ́n di alágbára ní ipa?
8Irú-ọmọ wọn fi ìdí kalẹ̀ ní ojú wọn pẹ̀lú wọn, àti ọmọ ọmọ wọn ní ojú wọn.
9Ilé wọn wà láìní ewu àti ẹ̀rù, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀pá ìbínú Ọlọ́run kò sí lára wọn.
10Akọ màlúù wọn a máa gùn, kì í sì tàsé; abo màlúù wọn a máa bí, kì í sì í ṣẹ́yun.
11Wọn a máa rán àwọn ọmọ wọn wẹ́wẹ́ jáde bí agbo ẹran, àwọn ọmọ wọn a sì máa jo kiri.