9Ilé wọn wà láìní ewu àti ẹ̀rù, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀pá ìbínú Ọlọ́run kò sí lára wọn.
10Akọ màlúù wọn a máa gùn, kì í sì tàsé; abo màlúù wọn a máa bí, kì í sì í ṣẹ́yun.
11Wọn a máa rán àwọn ọmọ wọn wẹ́wẹ́ jáde bí agbo ẹran, àwọn ọmọ wọn a sì máa jo kiri.
12Wọ́n mú ohun ọ̀nà orin, ìlù àti haapu; wọ́n sì ń yọ̀ sí ohùn fèrè.
13Wọ́n n lo ọjọ́ wọn nínú ọrọ̀; wọn sì lọ sí ipò òkú ní àlàáfíà.