Jobu 30

Wọ́n rù nítorí àìní àti ìyàn wọ́n ń rìn káàkiri ní ilẹ̀ gbígbẹ ní ibi ìkọ̀sílẹ̀ ní òru.

Job 30:3 (UKJV) For lack and famine they were solitary; fleeing into the wilderness in former time desolate and waste.

1“Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, àwọn tí mo gbà ní àbúrò ń fi mí ṣe ẹlẹ́yà baba ẹni tí èmi kẹ́gàn láti tò pẹ̀lú àwọn ajá nínú agbo ẹran mi.

2Kí ni ìwúlò agbára ọwọ́ wọn sí mi, níwọ̀n ìgbà tí agbára wọn ti fi wọ́n sílẹ̀?

3Wọ́n rù nítorí àìní àti ìyàn wọ́n ń rìn káàkiri ní ilẹ̀ gbígbẹ ní ibi ìkọ̀sílẹ̀ ní òru.

4Àwọn ẹni tí ń já ewé iyọ̀ ní ẹ̀bá igbó; gbogbo igikígi ni oúnjẹ jíjẹ wọn.

5A lé wọn kúrò láàrín ènìyàn, àwọn ènìyàn sì pariwo lé wọn lórí bí ẹní pariwo lé olè lórí.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.