Jobu 30

A lé wọn kúrò láàrín ènìyàn, àwọn ènìyàn sì pariwo lé wọn lórí bí ẹní pariwo lé olè lórí.

Job 30:5 (UKJV) They were driven forth from among men, (they cried after them as after a thief;)

3Wọ́n rù nítorí àìní àti ìyàn wọ́n ń rìn káàkiri ní ilẹ̀ gbígbẹ ní ibi ìkọ̀sílẹ̀ ní òru.

4Àwọn ẹni tí ń já ewé iyọ̀ ní ẹ̀bá igbó; gbogbo igikígi ni oúnjẹ jíjẹ wọn.

5A lé wọn kúrò láàrín ènìyàn, àwọn ènìyàn sì pariwo lé wọn lórí bí ẹní pariwo lé olè lórí.

6A mú wọn gbe inú pàlàpálá òkúta àfonífojì, nínú ihò ilẹ̀ àti ti òkúta.

7Wọ́n ń dún ní àárín igbó wọ́n kó ara wọn jọ pọ̀ ní abẹ́ ẹ̀gún neteli.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.