5A lé wọn kúrò láàrín ènìyàn, àwọn ènìyàn sì pariwo lé wọn lórí bí ẹní pariwo lé olè lórí.
6A mú wọn gbe inú pàlàpálá òkúta àfonífojì, nínú ihò ilẹ̀ àti ti òkúta.
7Wọ́n ń dún ní àárín igbó wọ́n kó ara wọn jọ pọ̀ ní abẹ́ ẹ̀gún neteli.
8Àwọn ọmọ ẹni tí òye kò yé, àní àwọn ọmọ lásán, a sì lé wọn jáde kúrò ní orí ilẹ̀.
9“Ǹjẹ́ nísinsin yìí, àwọn ọmọ wọn ń fi mí ṣe ẹlẹ́yà nínú orin; àní èmi di ẹni ìṣọ̀rọ̀ sí láàrín wọn.